Ẹrú Kíkó
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ẹrú kíkó níṣe pẹ̀lú kí àwọn ológun kó àwọn ènìyàn kúrò ní agbègbè tí wọ́n ń gbé lọ sọ wọ́n di ẹrú ní ilẹ̀ ibòmíràn. Tẹ́lẹ̀, èyí jẹ́ ohun tó tọ́ tàbí tí ó jẹ mọ́ ogun jíjá, ṣùgbọ́n lóde-òní ẹ̀ṣẹ̀ ni ó jẹ́. Láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ni ẹrú kíkó ti wà. Ní ilẹ̀ Sumer (tí a mọ̀ sí Iraq lóde-òní) ni àkọsílẹ̀ ẹrú kíkó ti wáyé jù lọ. Ìjénìyàngbé àti àwọn ẹrú láti ara ogun jíjà ni ó ṣokùnfà àwọn ẹrú ilẹ̀ Áfíríkà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣọ̀fà àti Ìjẹniníyà náà wà lára àwọn ohun tí ó bí ẹrú.
Ìmọ̀-ẹ̀rọ àti àwọn àyípadà tó ti ń dé bá àṣà àti ìṣe ti ń mu kí kíkó ẹrú àti ìfènìyàn ṣọfà máa parẹ́.