Anne Revere
From Wikipedia, the free encyclopedia
Anne Revere (oṣù kẹfà, ọjọ́ márùn-ún-dín-lọ́gbọ̀n-lọ́gbọ̀n, ọdún 1903 sí oṣù Kejìlá ọjọ́ méjì-dín-lógún, ọdún 1990) jẹ́ òṣèré ará Ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ọmọ ẹgbẹ́ tí ń lọ síwájú nínú ìgbìmọ̀ ti Screen Actor's Guild. Ó jẹ́ gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ lórí Broadway àti àwọn ipa rẹ̀ bí ìyá nínú àwọn eré ìwòrán lẹ́sẹsẹ tó ní iyì. Àtakò aláríwísí ti Ìgbìmọ̀ House Un-American Activities Committee, orúkọ rẹ̀ hàn ní Red Channels: The Report on Communist Influence ní Rédíò àti lórí tẹlifísàn ní odún 1950.
Revere gba Ààmì Eye Akádẹ́mì fún ipa àtìlẹ́yìn rẹ̀ nínú fíìmù National Velvet (ọdún 1945). Wọ́n sì yàn án ní ẹ̀ka kan náà fún "The Song of Bernadette" (ní ọdún 1943) àti Gentleman's Agreement (ní ọdún 1947). Ó gba àwọ́ọ̀dù Tony fún iṣẹ́ rẹ̀ nínú Lilian Hellman's play toys in the Attic ní ọdún 1960.